Ezekiel 23:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí wọ́n ti ṣe àgbèrè, wọ́n sì ti paniyan; wọ́n ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn, wọ́n sì ti pa àwọn ọmọ wọn ọkunrin tí wọ́n bí fún mi, bọ oriṣa wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pe, nwọn ti ṣe panṣaga ẹ̀jẹ si mbẹ lọwọ wọn, ati nipasẹ oriṣa wọn ni nwọn ti ṣe panṣaga, nwọn si ti jẹ ki awọn ọmọ wọn, ti nwọn bi fun mi, kọja lãrin iná fun wọn, lati run wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn orìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fúnni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.