Ezekiel 23:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí oriṣa wọn, ni wọ́n tún wá sí ilé ìsìn mi, tí wọ́n sọ ọ́ di eléèérí. Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní ilé mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe igbati nwọn pa awọn ọmọ wọn fun oriṣa wọn, nigbana ni nwọn wá ni ijọ kanna si ibi mimọ́ mi, lati sọ ọ di àilọwọ; si kiye si i, bayi ni nwọn ṣe lãrin ile mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkúlò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.