Ezekiel 23:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀sọ́ iyebíye sára,