Ezekiel 23:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìbìkítà ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lọ́dọ̀ yín, àwọn ọkunrin ọ̀mùtí lásánlàsàn kan sì wá láti inú aṣálẹ̀, wọ́n kó ẹ̀gbà sí àwọn obinrin lọ́wọ́, wọ́n fi adé tí ó lẹ́wà dé wọn lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn pa rọ́rọ wà lọdọ rẹ̀: ati pẹlu enia lasan li a mu awọn Sabeani lati aginjù wá, ti nwọn fi jufù si apá wọn, ati ade daradara si ori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn.