Ezekiel 23:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ pe ogunlọ́gọ̀ eniyan lé wọn lórí kí wọ́n ṣẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ẹgbẹ kan tọ̀ wọn wá, emi o si fi wọn fun wọn lati kó wọn lọ, ati lati bà wọn jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyàn kénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun.