Ezekiel 23:49 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si san ẹ̀san ìwa ifẹkufẹ nyin si ori nyin, ẹnyin o si rù ẹ̀ṣẹ oriṣa nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Olódùmarè.”