Ezekiel 23:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i.