Ezekiel 24:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.