Ezekiel 24:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, iwọ kọ orukọ ọjọ na, ani ọjọ kanna yi: ọba Babiloni doju kọ Jerusalemu li ọjọ kanna yi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí Ọba Bábílónì náà ti dojúti Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ yìí gan an.