Ezekiel 24:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ títayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáànú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.