Ezekiel 24:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí i yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò sọ̀fọ̀ tàbí sunkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedédé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrin ara yín.