Ezekiel 24:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu, iwọ ọmọ enia, kì yio ha ṣe pe, ni ijọ na nigbati mo ba gbà agbara wọn, ayọ̀ ogo wọn, ifẹ oju wọn, ati eyiti nwọn gbe ọkàn wọn le, ọmọ wọn ọkunrin, ati ọmọ wọn obinrin, kuro lọdọ wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Pẹ̀lúpẹ̀lù ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn,