Ezekiel 24:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú, kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà, kí o bọ ẹran náà, bọ̀ ọ́ teegunteegun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mu ninu agbo-ẹran ti o jọju, ko awọn egungun sabẹ rẹ̀, si jẹ ki o hó dãdã, si jẹ ki nwọn bọ̀ egungun rẹ̀ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran. Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀; sì jẹ́ kí ó hó dára dára sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.