Ezekiel 24:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbé ni fun ilu ẹlẹjẹ na, fun ìkoko ti ifõfo rẹ̀ wà ninu rẹ̀, ti ifõfo rẹ̀ kò dá loju rẹ̀: mu u jade li aján li aján; máṣe dìbo nitori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà, fún ìkòkò náà tí èrúru wà nínú rẹ̀ tí èrúru kò dà kúrò lójú rẹ̀! Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí má ṣe ṣà wọ́n mú.