Ezekiel 25:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si gbe ẹ̀san mi le ori Edomu lati ọwọ́ Israeli enia mi: nwọn o si ṣe ni Edomu gẹgẹ bi ibinu mi, ati gẹgẹ bi irúnu mi; nwọn o si mọ̀ ẹ̀san mi, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò gbẹ̀san lára Édómù láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, wọn sì se ṣsi Édómù gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi: wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”