Ezekiel 25:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wí fún wọn báyìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí; nítorí pé ẹ̀ ń yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ẹ̀ ń yọ ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ẹ sì ń yọ ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n kó o lọ sí ìgbèkùn;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wi fun awọn ara Ammoni pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun: Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti iwọ wipe, Aha, si ibi mimọ́ mi, nigbati o di àilọwọ, ati si ilẹ Israeli, nigbati o di ahoro; ati si ilẹ Juda, nigbati nwọn lọ ni ìgbekun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wí fún àwọn ará Ámónì pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run tí ó wí pé: Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Júdà, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,