Ezekiel 25:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí náà, n óo fà yín lé àwọn ará ilẹ̀ ìlà oòrùn lọ́wọ́, ẹ óo sì di tiwọn. Wọn óo pa àgọ́ sí ààrin yín; wọn óo tẹ̀dó sí ààrin yín; wọn óo máa jẹ èso oko yín, wọn óo sì máa mu wàrà yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, nitorina emi o fi ọ le awọn enia ilà-õrùn lọwọ fun ini, nwọn o si gbe ãfin wọn kalẹ ninu rẹ, nwọn o si ṣe ibugbe wọn ninu rẹ: nwọn o jẹ eso rẹ, nwọn o si mu wàra rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kíyèsí i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ: wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.