Ezekiel 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo sọ ìlú Raba di pápá àwọn ràkúnmí, àwọn ìlú Amoni yóo sì di pápá ẹran. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ Rabba di ibujẹ fun ibakasiẹ, ati awọn ọmọ Ammoni di ibùsun fun agbo-ẹran: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.