Ezekiel 26:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọ̀pọ awọn ẹṣin rẹ̀ ẽkuru wọn yio bò ọ: odi rẹ yio mì nipa ariwo awọn ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́, ati kẹkẹ́ ogun, nigbati yio wọ̀ inu odi rẹ lọ, gẹgẹ bi enia ti wọ̀ inu ilu ti a fọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹsin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti o di fífọ́ pátapáta.