Ezekiel 26:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fi ọrọ̀ rẹ ṣe ikogun, ati òwo rẹ ṣe ijẹ ogun; nwọn o si wo odi rẹ lulẹ, nwọn o si bà ile rẹ daradara jẹ: nwọn o si ko okuta rẹ, ati ìti igi-ìkọle rẹ, ati erùpẹ rẹ, dà si ãrin omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú òkun.