Ezekiel 26:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn ọmọ-alade okun yio sọ̀kalẹ kuro lori itẹ́ wọn, nwọn o si pa aṣọ igunwà wọn tì, nwọn o si bọ́ ẹ̀wu oniṣẹ-ọnà wọn: nwọn o fi ìwariri bò ara wọn; nwọn o joko lori ilẹ, nwọn o si warìri nigba-gbogbo, ẹnu o si yà wọn si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ aládé etíkun yóò sọ̀ kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn tì wọn yóò sì bọ́ àwọn ẹ̀wù wọn tí a ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jòkòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.