Ezekiel 26:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé: Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun, ìwọ ìlú olókìkí, ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun, ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ, àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si pohunrere-ẹkun fun ọ, nwọn o si wi fun ọ pe, Bawo li ati pa ọ run, iwọ ti awọn èro okun ti ngbe inu rẹ̀, ilu olokikí, ti o lagbara li okun, on ati awọn ti o gbe inu rẹ̀, ẹniti o mu ẹ̀ru wọn wá sara gbogbo awọn ti o pàra ninu rẹ!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “ ‘Báwo ni a se pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.