Ezekiel 26:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nigbati emi o sọ ọ di ahoro ilu, gẹgẹ bi ilu wọnni ti a kò gbe inu wọn; nigbati emi o si mu ibú wá sori rẹ, ati omi nla yio si bò ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,