Ezekiel 26:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi o bá mu ọ walẹ pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, pẹlu awọn enia igbãni, ti emi o si gbe ọ kà ibi isalẹ ilẹ aiye, ni ibi ahoro igbãni, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò, ki a máṣe gbe inu rẹ mọ́: emi o si gbe ogo kalẹ ni ilẹ awọn alãye;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ ibi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.