Ezekiel 26:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, Ọba àwọn Ọba, dide sí Tírè pẹ̀lú ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.