Ezekiel 26:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì fi idà ṣá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkítì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ.