Ezekiel 27:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékì wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gámádì, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé.