Ezekiel 27:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.