Ezekiel 27:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda, ati ilẹ Israeli, awọn li awọn oniṣòwo rẹ, alikama ti Minniti, ati Pannagi, ati oyin, ati ororo, ati balmu, ni nwọn fi ná ọjà rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.