Ezekiel 27:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li awọn oniṣòwo rẹ li onirũru nkan, ni aṣọ alaro, ati oniṣẹ-ọnà, ati apoti aṣọ oniyebiye, ti a fi okùn dì, ti a si fi igi kedari ṣe, ninu awọn oniṣòwo rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.