Ezekiel 27:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé, o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si wi fun Tire pe, Iwọ ti a tẹ̀do si ẹnu-ọ̀na okun, oniṣòwo awọn orilẹ-ède fun ọ̀pọlọpọ erekùṣu, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ Tire, iwọ ti wipe, emi pé li ẹwà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ìwọ Tírè wí pé “Ẹwá mi pé.”