Ezekiel 27:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ, wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí, wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ, inú wọn yóo sì bàjẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ wọn yóò wọ aṣọ yíya wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú ìkoro ọkàn nítorí rẹ pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.