Ezekiel 27:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ, àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹ kí omi má baà wọnú rẹ̀. Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn àgba Gebali, ati awọn ọlọgbọn ibẹ̀, wà ninu rẹ bi adikọ̀ rẹ: gbogbo ọkọ̀ òkun pẹlu awọn ara ọkọ̀ wọn wà ninu rẹ lati ma ṣòwo rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àgbà Gíbálì, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú òkun àti àwọn atukọ̀-òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.