Ezekiel 28:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nítorí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ọba Tire. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘O ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà pípé, o kún fún ọgbọ́n, o sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí o kò ní àbùkù kankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náà o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà