Ezekiel 28:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ; sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì, àti jásípérì, sáfírè, émérálídì àti káríbúnkílì, àti wúrà ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.