Ezekiel 28:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tírè pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè simi ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà ní àárin gbùngbùn òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.