Ezekiel 28:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì, a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ. Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní OLÚWA, Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,