Ezekiel 28:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹ èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹ ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹ pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni OLÚWA.