Ezekiel 28:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nigbati emi o bá ti kó ile Israeli jọ kuro lãrin awọn orilẹ-ède ti a tú wọn ká si, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu wọn loju awọn keferi, nigbana ni nwọn o gbé ilẹ wọn ti mo ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Nígbà tí èmi yóò bá ṣa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàárin wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkalára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jákọ́bù.