Ezekiel 28:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si ma gbé inu rẹ̀ ni ibalẹ-aiya, nwọn o si kọ́ ile, nwọn o si gbìn ọgbà àjara; nitõtọ, nwọn o wà ni ibalẹ-aiya, nigbati emi bá ti mu idajọ mi ṣẹ si ara awọn ti ngàn wọn yi wọn kakiri, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi sẹ sí ara àwọn tí ń ṣáátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn.’ ”