Ezekiel 28:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́