Ezekiel 29:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro patapata, n óo jẹ́ kí àwọn ìlú rẹ̀ di ahoro fún ogoji ọdún. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti káàkiri gbogbo ayé, n óo sì tú wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ati ilu rẹ̀ yio si di ahoro li ãrin awọn ilu ti o di ahoro li ogoji ọdun: emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin gbogbo orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin gbogbo ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sọ ilẹ Éjíbítì di ọ̀kan ní àárin àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sáàárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárin gbogbo ilẹ̀.