Ezekiel 29:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun ni yóo rẹlẹ̀ jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kò ní lè gbé ara rẹ̀ ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́. N óo sọ wọ́n di kékeré tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè jọba lórí orílẹ̀-èdè kankan mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si jẹ ijọba ti o rẹ̀lẹ jù ninu awọn ijọba; bẹ̃ni kì yio si gbe ara rẹ̀ ga mọ́ sori awọn orilẹ-ède: nitori emi o dín wọn kù, ti nwọn kì yio fi ṣe olori awọn orilẹ-ède mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, ti wọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.