Ezekiel 29:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ijipti kò ní tó gbójú lé fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Ijipti yóo máa rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, pé wọ́n ti wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Ijipti tẹ́lẹ̀ rí. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì yio si jẹ igbẹkẹle fun ile Israeli mọ́, ti o mu aiṣedẽde wọn wá si iranti, nigbati nwọn o ba wò wọn: ṣugbọn nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Éjíbítì kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Ísírẹ́lì mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedédé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run.’ ”