Ezekiel 29:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, Nebukadinesari ọba Babiloni mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Tire kíkankíkan. Wọ́n ru ẹrù títí orí gbogbo wọn pá, èjìká gbogbo wọn sì di egbò. Sibẹ òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò rí èrè kankan gbà ninu gbogbo wahala tí wọ́n ṣe ní Tire.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, Nebukadresari ọba Babiloni mu ki ogun rẹ̀ sìn irú nla si Tire: gbogbo ori pá, ati gbogbo èjiká bó: sibẹsibẹ on, ati awọn ogun rẹ̀, kò ri owo ọ̀ya gbà, lati Tire fun irú ti o ti sìn si i:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tírè. Gbogbo ori pá, àti gbogbo èjìká bó, ṣíbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owo ọ̀yà gbà láti Tírè fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.