Ezekiel 29:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo fi ilẹ̀ Ijipti lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó àwọn eniyan rẹ̀ lọ, yóo sì fi ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ṣe ìkógun, èyí ni yóo jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ilẹ Egipti fun Nebukadresari ọba Babiloni; yio si kó awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ati ikógun rẹ̀, ati ijẹ rẹ̀; yio si jẹ owo ọ̀ya fun awọn ogun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, Èmi yóò fi Éjíbítì fún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.