Ezekiel 29:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní ọjọ́ náà, n óo gbé alágbára kan dìde ní Israẹli, n óo mú kí ìwọ Isikiẹli ó sọ̀rọ̀ láàrin wọn. Nígbà náà, wọn yóo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na li emi o mu ki iwọ Israeli rú jade, emi o si fun ọ ni iṣínu li ãrin wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ilé Ísírẹ́lì ní agbára, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárin wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”