Ezekiel 29:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo gbé ọ jù sinu aṣálẹ̀, ìwọ ati gbogbo ẹja inú odò Naili rẹ. Ẹ ó bọ́ lulẹ̀ ninu pápá tí ó tẹ́jú. Ẹnìkan kò sì ní kó òkú yín jọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin yín. Mo ti fi yín ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ ọ nù si aginjù, iwọ ati gbogbo ẹja odò rẹ: iwọ o ṣubu ni gbangba oko: a kì yio si kó ọ jọ, bẹ̃li a kì yio si ṣà ọ jọ: emi ti fi ọ ṣe onjẹ fun awọn ẹranko igbẹ́, ati fun awọn ẹiyẹ oju ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí ihà ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oùnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.