Ezekiel 3:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ẹmi na gbe mi soke, o si mu mi kuro, mo si lọ ni ibinujẹ, ati ninu gbigbona ọkàn mi; ṣugbọn ọwọ́ Oluwa le lara mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle OLÚWA ni ara mi.