Ezekiel 3:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kébárì níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Ábíbì. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrin wọn pẹ̀lú ìyànu, fún ọjọ́ méje.